
Gómìnà tuntun tí àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ Edo ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Ọ̀gbẹ́ni Okpebolo ti sọ pé pèlú bí ariwo,ìjà,jàádì òhun làkáádí ṣe gba gbangba àti kọ̀rọ̀kọ́ńdú ìpínlẹ̀ náà lásìkò ètò ìdìbò sí ipò Gómìnà tó kọjá,ọpẹ́ ni fún Jèhófà pé àwọn ènìyàn kò di olóògbé lásìkò náà.O ní bí ènìyàn bá fi ètò ìdìbò náà wé gbogbo eléyìí tó ti máa ń wáyé tẹ́lẹ̀, yóò rí i pé ọpẹ́ ló yẹ fún Ọlọ́run.
Okpebolo ni “Ilá ló ń tojú olówó rẹ̀ í kù,ikàn ló ń tojú olówó rẹ̀ rèwàlẹ̀ àṣà, ohun burúkú ni kí màjèṣín máa tọjú òbí rọ̀run,Mo dúpẹ́ pé àwọn ògo ọjọ́ ọ̀la ìpínlẹ̀ Edo kò di ohun ètùtù fún ìbò” Okpebolo tẹ̀ síwájú pé ìgbé ayé rere àwọn tẹrú-tọmọ ìpínlẹ̀ Edo ló múmú láyà Òun.
Gómìnà Àdìbòyàn náà fojú ọ̀rọ̀ yìí léde nígbà tí ó ṣe àbẹwò “Ẹ ṣehun,a dúpẹ́ “sí alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ilẹ̀ Nàìjíríà, Dokita Umar Ganduje lọ́ọ́fíìsì rẹ̀ nílùú Abuja .
Nígbà tí Ó ń fèsì, Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ilẹ̀ Nàìjíríà, Ganduje sọ pé àáyá bẹ́ sílẹ̀,ó bá sáré ni kí Gómìnà náà fi ètò ìṣèjọba rẹ ṣe nítorí àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ rẹ̀ ń retí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tó dára láti ọ̀dọ̀ ìjọba rẹ nitori òrùgbẹ ìjọba onítẹ̀síwájú ń gbẹ àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ náà láti ọjọ́ pípẹ́ wá.

Ó ní kí ó má se máa dọdẹ Gómìnà tó fẹ́ kógbá sílé ṣugbọn kó gbájúmọ́ bí ayé awọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣe ní ìtumọ.Ganduje ní “Ẹni tó bá fẹ́ mú ènìyàn wọ inú ìgbẹ́ ní túláàsì, ẹ̀yìn rẹ̀ ni yóò fi lànà” Ó wá ṣe àdúrà pé àṣeyọrí tí alákàn ń sepo ni yóò ṣe.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
