Ẹ má fi Ayé ba Ọ̀run Jẹ́: Àlùfáà kìlọ̀ fún Àwọn Onígbàgbọ́

Àlùfáà Àgbà ìjọ Anglican kan ní Dáósísì Àkúrẹ́, Àlùfáà (Dókítà) Fágbèmí ti rọ àwọn Onígbàgbọ káàkiri àgbáyé láti ta kété sí ohun yòówù tó bá le mú wọn pàdánù ijọba ọ̀run.

Àlùfáà (Dókítà)Fágbèmí

Àlùfáà Fágbèmí yajúyamú ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń wàásù lórí bó ti ṣe pàtàkì tó láti jẹ Alábàápín nínú ìjọba ayérayé.Lónì-ín ọjọ́ ketàdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹwàá ọdún 2024 ni Àlùfáà yìí fojú ọ̀rọ̀ yìí léde nínú ìwàásù rẹ̀ tò wáyé nínú ìjọ All Saints Chapel,Bishop Court,Alágbàká, Àkúrẹ́

Ìríjú Ọlọ́run náà tún sọ pé “Ìwọ̀nba ni kí á lépa ohun ayé yìí mọ nitori ohun ayé yi ò bá ayé lọ.Bí a ti ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí wa tí inú wa ń dùn ni a ń sún mọ́ sàréè;kí olójú sì tó ṣẹ́jú pẹ́, ikú yóò ti wọlé wẹrẹ́”

Fágbèmí ní “ó dára láti fi ìṣúra wa sí Ọ̀run nibi ti kòkòrò òhun ìpáàrà kò ti ni bàá jè ju ki a máa ko ọrọ̀ jọ,láìmọ ẹní tí yi ò lò ó gbẹ̀yìn lọ

2 thoughts on “Ẹ má fi Ayé ba Ọ̀run Jẹ́: Àlùfáà kìlọ̀ fún Àwọn Onígbàgbọ́”

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×