
Bí Nnkan kò bá ṣe Àjànàkú,a kìí déédé rí awọ Erin lórí àtẹ̀,Òwe yìí ló dífá fún ìyọnípò àwọn Mínísítà márùn-ún ti ìjọba àpapọ̀ gba ìjẹ lẹ́nú wọn lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tó jáde láti ọ́ọ́fíìsì Ààrẹ ṣe ṣàlàyé, Èrò ará ìlú nípa ìhùwàsí ati àìmúyányán tó àwọn Mínísítà náà ló gba iṣẹ́ lọ́wọ́ wọn.
Olùdámọ̀ràn fún Ààrẹ Tinubu lórí ètò ìròyìn àti ìbáraẹnisọ̀rọ̀,Báyọ̀ Ọnànúgà ló sísọ lójú eégún ọ̀rọ̀ yìí nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìkànnì abẹ́yẹfò X rẹ̀ lánà-án.Ó ní ìtàkùn ayélukara kan wà ti àwọn ará ìlú fi máa ń ṣàlàyé bí àwọn Mínísítà bá ti kún ojú òṣùwọ̀n tó pẹ̀lú èrò wọn lórí ohun tí wọ́n fi kí ìjọba gbé ní ìgbésẹ̀ lórí Mínísítà kọ̀ọ̀kan.Ìgbéléwọ̀n kóówa wọn tó fẹ́rẹ̀ ló ṣokùnfà ìyọnípò wọn.
Lẹ́yẹ-ò-ṣọkà sì ni Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú ti fi orúkọ àwọn mìíràn tí yóò rọ́pò wọn ṣọwọ́ sí ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin. Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà,Godswill Akpabio si ti ka lẹta ti Ààrẹ kọ fún ìyànsípò àwọn Mínísítà tuntun náà sí etígbọ̀ọ́ àwọn ọmọ ilé lónì-ín ọjọ́ Ọjọ́bọ ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹwàá.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
