Nítorí Owó, Ọdọ́mọkùnrin kan Pa Àbúrò Ìyá Rẹ̀

Alhaji Wasiu Àdìgún

Gẹ́gẹ́ bíi odò ni omi ojú ṣe ń sàn ní ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí nibi tí àṣírí ikú ti ó pa ọkunrin gbajúgbajà oníṣòwò hóró kan Alhaji Wasiu Àdìgún ti tú tí wọn sì wú òkú rẹ̀ jáde lábẹ́ àgbàdo tí wọ́n bò ó mọ́.

Naija notes Yorùbá gbọ́ pé ọmọ àǹtí rẹ̀ ti ó ń gbé ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ló lù ú ní igi pa látẹ̀yìn pẹ̀lú ète àtigbé òbìtìbítí mílíọ̀nù náírà tí wọ́n gbé fún Alhaji Wasiu láti ra káṣú lọ .

Ní kété tí ó ṣe iṣẹ́ burúkú yìí tan, tí ó sì bo òkú rẹ̀ mọ́ inú àgbàdo, ló wá gbé àtowó àti mọ́tò olóògbé sá lọ tí ẹnikẹ́ni kò sí mọ ibi ti ó wà titi di asiko ti a ń kó ìròyìn yìí jọ.

Lẹyìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ tí wọ́n ti ń wa ọkùnrin yìí ni wón tó rí i nínú àgbàdo.Won ti fi òrò náà tó àwọn agbófinró létí.

Ènìyàn dáradàra ni Alhaji Wasiu Àdìgún nígbà ayé rẹ̀.Òun sì ní alága àwọn tó ń ra hóró kaṣú, àgbàdo,jéró àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ní ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ àti agbègbè rẹ̀.

1 thought on “Nítorí Owó, Ọdọ́mọkùnrin kan Pa Àbúrò Ìyá Rẹ̀”

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×