
Àlùfáà àgbà tí ìjọ ECWA Omu-Aran, Rev’d J.O Babádé ti sọ yanya pé dandan ni ikú àti pé Àwayeiku kan kò sí fún gbogbo ènìyàn.Òní ni ìríjú Ọlọ́run yìí sàlàyé gbólóhùn yìí nibi ayẹyẹ ìsìnkú mòmò Comfort Oyelaran Olawuyi tó wáyé ní ìjọ ECWA, Òkò loni-in ọjọ́ Jímọ̀n-ọ̀n ojọ́ kejidinlogun osù kẹwàá ọdún yìí.
Ènìyàn Ọlọ́run náà ṣe àlàyé pé kò sí adùn kan láyé yìí ju kí á jẹ́ ẹnìyàn Ọlọ́run,kí á sí ṣe oore tó ní Álùbáríkà fún àwọn ènìyàn lọ.

Ó tẹ̀ síwájú pé kò sí ìrọ̀rùn kan láyé ju pé kí á jẹ́ olódodo àti olóòótọ sí àwọn ìlànà àti àṣẹ Olúwa lọ
Ọdún 2033 ni a bí Comfort Oyelaran Olawuyi, ó lo àádọ́rùn-ún ọdún láyé kò tó di pé ikú pa ojú rẹ̀ dé.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
