Nibi ti Mo ba dé yìí;Ẹ̀rù ikú Kò bà mí Mọ́….Ṣóyínká

Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Ṣóyínká

Pàràkòyí onimọ̀ iṣẹ́ ọnà àti Lítíréṣọ̀ nnì, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Ṣóyínká ti sọ pé ‘Pa á jẹ́,bà á lẹ́rù,ìhàlẹ̀ ni,kò sí ikú tí yóò pa àgbà tí a kò nii bá Poolo orí rẹ̀ níbẹ̀’ Nibi ti òun bá a dé yìí,ẹ̀rù ikú kò ba òun mọ́.

Ó tún sọ ìdí pàtàkì tí òun fi kọ́ ilé sí ibi ìdákẹ́jẹ́ẹ́.Gege bó ti wí,o ní ibí tó takété sí ariwo tí òun kọ́ ilé sí wà lára ohun tó ṣe okùnfà àṣeyọrí tí òun ṣe níbi iṣẹ́ tí òun yàn láàyò.

Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́kan-ò-jọ̀kan yìí jáde láti ẹnu igi ìwé,gbòǹgbò imọ̀ náà nígbà tí ó ń dahùn ìbéèrè tí àwọn Oníròyìn CNN tàkòtó ránṣẹ sí í nínú ilé rẹ̀ ní ìlú Abẹ́òkúta.

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà wà lára Àlàkalẹ̀ ètò láti fi ṣe àmìn ayẹyẹ ààdọ́rùn-ún ọdún tí Ònkòwé náà ti wà lókè èrùpẹ̀.

Ṣóyínká ní ”Lóòótọ́ ni mo ti pé àádọ́rùn-ún ọdún,síbẹ̀,koko lara ọta mí lẹ Mọ dúpẹ́ pé pírí ni olongo mi ń jí ṣùgbón mo ti gbára dì fún ikú nítorí mo mọ̀ pé òun ni òpin gbogbo wa.”

Òlùkọ́ àgbà Fasiti tó ti fẹ̀yìn ti ni Wọlé Ṣóyínká.Akéwì, Òṣèré,Ajàfẹ́tọ̀ọmọ́nìyàn,Òǹkọ̀tàn àti

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×