
Ètò ìdìbò sí ipò Alága ìjọba ìbílẹ̀ àti àwọn kánsílọ̀ ló ti wáyé yíká ipinle Rivers loni-in.
Bí-ó-tilẹ̀-jẹ́-pé ìdájọ́ ilé ẹjọ gíga kan ni ìlú Abuja kò fara mó bí ètò ìdìbò náà ṣe wáyé.
Ohun tí ó fa jágbánrúju ni rúkèrúdò tó ń wáyé láàrin Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers ,Fubara àti Babańgbẹ̀jọ́ọ rẹ̀, ìyẹn Mínísítà fún olú ìlú wa Nyesom Wike .
Ètò Òṣèlú ìpínlè Rivers lohun tí àwọn oníròyìn n jẹ lẹ́nu bí ẹní jẹ gúgúrú lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
