L’Óǹdó: Ìṣẹ̀lẹ̀ Omíyalé fẹ̀mí òhun Dúkìá ṣòfò.

Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àgbègbè tí ó wà ní ìlú Oǹdó ni ìṣẹ̀lẹ̀ Omíyalé tó ṣẹlẹ̀ lánà-án fọwọ́ bà.Láti Ọlọ́runṣọlá ní Yaba dé Odòjọmu dé Lípàkálà gba àwọn agbègbè kan ní Fágùn.Òpópónà Ifẹ̀ àtí Ìta ńlá.

Òkú adìẹ kò mọ ẹní tó ń tu ú lánà-án níbi tí olúkúlùkù ti ń jà fún orí ara rẹ̀ ki òun àti dúkìá rẹ̀ má ṣe di ti Olúwẹri.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n ṣe ìnáwó ní òjò náà ba ọjọ́ ayẹyẹ wọn jẹ́

Ìjọba ìpínlẹ̀ Oǹdó ti wá pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ tó wà ní ìgbánnu àyíká láti tètè ṣe ohun tó bá yẹ láti dènà irúfé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lọ́jọ́ iwájú.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×