
Ààrẹ ilẹ̀ yii, Asíwájú Bọ́lá Tinúbú tí jàwé akìwọwọ fún àwọn Ajínigbé Boko-haram àti Àṣẹ̀rùbàlú Bándíìtì kí wọ́n so ewé agbéjẹ́ẹ́ mọ́wọ́,bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ọwọ́ pálábá wọn kò ní pẹ́ ṣégi.
Abuja ni Ààrẹ ti laago ìkìlọ yìí lánà-àn nígbà tó ń lu àwọn ọmọ olóógun lọ́gọ ẹnu lórí àṣeyọrí tí wọ́n ṣe fún bí wọn ti já okùn ẹ̀mí àwọn èèkàn bíi mélòó kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ aṣẹ̀rùbàlú méjèèjì.
Tinúbú ní ikoko kò ní gba omi kó gba ẹyìn kó tún gba ṣọṣọ fún ìjọba ilẹ̀ Nàìjíríà àti àwọn Ajáléonílé-bo-tirẹ̀-lẹ́yìn tó ń pon’mi òkè rú todò yíká ilẹ̀ wa.
Gégé bí Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú ṣe wí,”A ti pàrọwà títí wọn kò gbọ́,eleyii ló fi yé wa pé ọmọ ilẹ̀ kìí sùn sí orí bẹ́ẹ̀dì àti pé lẹ́hìn àpónlé,àbùkù ló kù” Èyí ni bí Ààrẹ ṣe fi tìbínú-tìbínú sọ̀rọ̀.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
