Tuntun ti dé o!Ẹ̀rọ  ń fọ Ènìyàn bí Ẹní fọṣọ .

Ọ̀kánjúwà ń dàgbà,ọgbọ́n ń rewájú, ilé iṣẹ́ imọ̀ ẹ̀rọ tó gbajumo nílẹ̀ Japan ti a mọ̀ sí Sanyo ti gbé àràmọ̀ǹdà ẹ̀rọ kan tí yóò máa wẹ ènìyàn tí yóò tún máa ṣe iṣẹ́ atora jáde.

Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ sàlàyé fún wa pé ọmọ tuntun kìí ṣe àkọ́pa fún àjẹ́, ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ yìí kan náà tí ṣe irúfẹ́ ẹ̀rọ awẹni-wẹ̀nìyàn bayii lọ́dún 1970.

Ẹ̀rọ tuntun yìí yóò máa kọrin àti lùlù sí àwọn tó bá ń lò ó létí bí ó bá ti ń wẹ̀ wọ́n tó sì ń to ara fún wọn .

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×