
Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà,Bọ́lá Tinúbú ti rọ àwọn Gómìnà gbogbo nilẹ̀ wa láti mú iṣẹ́ àgbẹ̀ lọ́kùnkúndùn.
Òwúrọ̀ òní ni Ààrẹ fojú ọrọ yìí léde nígbà tí ó ń bá àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọrọ láti ṣe àmìn sí ayẹyẹ òmìnira ilẹ̀ Nàìjíríà ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlélọ́gọ́ta irú rẹ̀.
Ààrẹ lu àwọn ìpínlẹ̀ bíi Niger,Kebbi,Kwara àtàwọn miiran lọ́gọ ẹnu fún ipa tí wọ́n ti kó l’ójúnà àtipèṣè ounjẹ yanturu kí ounjẹ le sùnwábọ̀ nílẹ̀ Nàìjíríà.Ààrẹ kò sàìrọ àwọn ìpínlẹ̀ tó kù kí wọ́n má ṣe káwọ́ gbera nítorí bí apá bá kún itan,a máa tó í pín.
Gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, ìjọba àpapọ̀ ti ṣetán láti kún ipinlẹ̀ yòówù tó bá ṣetán lówó l’ójúnà àtipèṣè ounjẹ yanturu.Láti mú kí èyí rọrùn, ìjọba kò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìpèsè ẹ̀rọ katakata fún lílò àwọn àgbẹ̀ lábẹ́lé.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
