Nítorí ìjákulẹ̀ Ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP Nínú Ìdìbò Edo: Gómìnà Obaseki sá lọ sí Venice

Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo, Godwin Obaseki àti ìyàwó rẹ̀ ti fi orile-ede Naijiria sílẹ̀ lọ sí orílẹ̀-èdè Venice.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye ló ti ń jà rọ̀ninrọ̀nìn lórí ohun tó le fa ìrìnàjò pàjáwìrì ti Gómìnà rìn yìí nítorí ẹni tó pẹ́ lóko ló ní ká dá àbákábàá sí òun àti pé ìfura ń bẹ níbi ìyàwó tí a fà fún ọkọ lọ́gànjọ́ òru.

Àwọn kan gbàgbọ́ pé nítorí ìjákulẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nínú ètò ìdìbò sí ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ náà tó kọjá lọ eleyii ti yóò jẹ́ kí àṣírí àparútu ti Gómìnà náà ti ṣe sílẹ̀ tú sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ ló jẹ́ kó tètè júbà ehoro nítorí ẹ̀hìn àgbà rèé,sàn ju ojú àgbà rèé lọ.

Tí ẹ kò bá gbàgbé, ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló jàwé Olúborí ninu ètò ìdìbò tó kọjá lọ náà.Gẹ́gẹ́ bíi ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò, yóò ṣòro fún Gómìnà tó ń bọ̀ láti da aṣọ bo ìhòòhò Obaseki.Ìbẹ̀rùbojo yìí ló mú kí Godwin tètè fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ kí ilẹ̀ tó mọ olórò s’óde.Ṣé ẹni tí a rí là ń mọ́ lójú.

Ẹ̀wẹ̀, ìròyìn tó jáde láti ilé ìjọba fi yé wa pé ìsinmi ìparí ṣáà, ìyẹn Terminal leave ni Gómìnà lọ fún.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ,ohun tó dájú tó Àdá ni pé Gómìnà Godwin Obaseki àti ìyàwó rẹ̀ ti fi Naijiria sílẹ̀.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×