
Hmmm! Ikú ti gbẹ̀mí ìyàwó Gómìnà ìpínlẹ̀ Akwa Ibom, Arábìnrin Patience Umo Eno.Àná ọjọ́ ọjóbọ ni Arábìnrin ọ̀hún jẹ́ ìpè Ẹlẹ́dàá látàrí àisàn ránpẹ́ nílé ìwòsan kan ní olú-ìlu ìpínlẹ̀ náà .
Alákòóso ọ̀rọ̀ ìròyìn ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom,Ini Ememobong ló fojú ọ̀rọ̀ yìí léde nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta ní kùtùkùtù òwúrò òní.
Ó ní “A fi tẹ̀dùntẹ̀dùn kéde ikú Obìnrin àkọ́kọ́ ní ìpínlẹ̀ yìí,Olùṣọ́ àgùtàn Arábìnrin Patience Umo Eno.Ẹni tó gbé ẹ̀mí mì nile ìwòsan kan níṣejú àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀. ìrọ̀lẹ́ àná ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà sẹlẹ̀.Bí-ó-tilẹ̀-jẹ́-pé ìnú Gómìnà bàjẹ́ gidigidi;síbẹ̀, ìjọba kò ní tẹ̀tì nínú akitiyan rẹ̀ láti mú kí ayé túbọ̀ rọrùn fún àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ yìí “

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
