Ìjọba Àpapọ̀ buwọ́ lu Àtúnṣe Ọ̀nà Adó-Ìfàkì-Ìkọ̀lé-Òmùò

Láìpẹ́ yìí ni ayé yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹdẹmuke fún àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ Èkìtì tó bá ń rin ojú ọ̀nà tó lọ sí Ìfàkì sí Ìkọ̀lé sí Òmùò titi dé ẹnu bodè Kogi láti ìlú Adó-Ekiti.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde kan tó jáde lẹ́yìn ìpàdé ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ìgbìmò aṣejoba tó ga jùlọ nílẹ̀ wa  nílùú Abuja se sọ, awọn ọnà tí a dárúkọ náà ni ìjọba àpapọ̀ ti fòǹtẹ̀ jàn tí àwọn Kọngílá yóò sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láìpẹ́.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì lu ìjọba àpapọ̀ lọ́gọ ẹnu fún àkànṣe iṣẹ náà pèlú bí iṣẹ́ ṣe ń tẹ̀ síwájú lójú ọ̀nà oníbejì Àkúrẹ́-Ìkẹ́rẹ́-Adó.

Nígbà tí Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Gómìnà lórí ètò ìròyìn, ọ̀gbẹ́ni Yínká Oyèbọ̀dé ń sọ̀rọ̀, ó ní Olúwa ló mọ̀-ọ́n-mọ̀ dé iṣẹ Gómìnà náà ládé nítorí kò fi Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú lọ́rùn sílẹ̀ láti rii pé ìdàgbàsókè tó lówúra bá ipinlẹ̀ Èkìtì.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×