
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn Mínísítà ìjọba àpapọ̀ ni jìnnìjìnnì ti mú nitori ìròyìn tó ń tàn kiri pe Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú ń gbèrò láti gba iṣẹ́ lẹ́nu wọn.
Agbẹnusọ fún Ààrẹ ìyen Báyọ̀ Ọnànúgà ló fojú òrò yíì léde ní ìlú Abuja lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.Ọnànúgà kò sọ gbèdéke àkókò kan pàtó tí ìyọninípò náà yóò wáyé ṣùgbọ́n ohun tó dájú tó Àdá ni pé wọn ó fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún wọn láìpẹ́.
Ìròyìn yìí ti gba oorun lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Mínísítà náà tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń sá eré àkọlùkọgbà kiri l’ójúnà kí ìjì àyípadà tó fẹ́ jà ọ̀hún má ṣe gbé wọn lọ.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
