Edo 2024:Ajọ INEC gbìyànjú…. Joshua

Ọ̀mọ̀wé Timothew Joshua

Olùkọ́ àgbà Yunifásítì kan, tíí tún ṣe Olórí ẹ̀ka tó ń kọ́ni ní ìmọ̀ nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú nílé ẹ̀kọ́ gíga jùlọ Wesley Yunifásítì tó wà ní ìlú  Oǹdó , Ọ̀mọ̀wé Timothew Joshua ti ṣe sàmọ́-ń-sáńgúdù sí àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ wa fún ọ̀nà Àparò- kan- ò -ga -jùkan-lọ tó fi ṣètò ìdìbò sí ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo tó wáyé lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.

Joshua fojú ọ̀rọ̀ yìí léde nígbà tí ó ń kópa lórí ètò Ọ̀rọ̀tóńlọ lórí ẹ̀rọ Rédíò Ẹ̀kí fm,nílùú Oǹdó lọ́jọ́ ajé ọ̀sẹ̀ yìí.

Olùkó àgbà náà ni gbogbo igbésẹ̀ tí àjọ ọ̀hún gbé ló wà ní ìbámu pẹlú òfin.Ó wá rọ àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ wa láti máa tẹ̀ síwájú nínú akitiyan re láti ṣètò ìbò lójúnà tí kò ni mú bayobáyó dání .

Nígbà tí ó ń dáhùn ìbéèrè lórí ohun tó fà á tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ṣe fìdí rẹmi nínú ètò ìdìbò Edo, Ọ̀mọ̀wé náà ní ìwà Mo-gbọ́n-tán-mo-mọ́n-án -tán Gómìnà Obaseki ló fa ìjákulẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú náà . O ní ìjà àjàdijú tí Gómìnà náà n bá Gbogbo èèyàn jà pẹ̀lú àimú ọ̀pọ̀ àwọn ìlérí tó ṣe lásìkò ìpolongo ìbò ṣẹ ló fa lílulẹ̀ náà.

Ó wá rọ àwọn ará ìlú lati máa dìbò ní ìbámu pẹlú ẹ̀rí ọkàn wọn . Kò sàìrọ awọn olóṣèlú láti máa gba ìjákulẹ̀ nigbàkúùgbà tó bá wáyé dípò fífi ẹnu tẹ́ḿbẹ́lú ilẹ̀ wa.

Lórí ọ̀rọ̀ Baba-ń-gbẹ̀ẹ́jọ̀, Joshua ní ọ̀rọ̀ náà kò lè tán nínú òṣèlú láíláí nitori omi tí a fi dá òṣèlú.O ní Baba-ń-gbẹ̀ẹ́jọ̀ gan-án wà nínú òṣèlú ilẹ Amẹ́ríkà, ó kàn jẹ́ pé ọ̀nà tí wọn ń gbà ṣe é ló yàtọ̀ sí ara wọn.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×