
Ọ̀rọ̀ ti dé ibi tí olóògûn ti ń sà á ní ilẹ̀ Yorùbá bayìí o.Láìfòlò fọhùn, èrò àwọn ará òkè ọya kò dára sí àwa èrò ìsàlẹ̀ níbi rárá.
Bí kò bá rí bí mo ti sọ yìí, tàbí sùgbón kò sí níbẹ̀ pé ó jọ bẹ́ẹ̀, nítorí ó jọ gáté kò jọ gàté ó fi ẹsẹ̀ méjèèjì tiro gátegàte.
Kín ló le fa kí àwọn ará òkè ọya máa fi tírélà lóòdù àwọn ọ̀dọ́ langba pẹ̀lú ọ̀kadà,màálù àti onírúurú ìbọn bíi AK 47 wá sí ìsàlẹ̀ níbi.Láti wá ṣe kinni?Àlùwàlá ológìnní,ọgbọ́n àtikẹ́ranjẹ ni o.
Igi gogoro má sì gún mi lójú, láti òkèrè ni a ti ń yẹ̀ ẹ́.Àgbàrá òjò kò ní òun kò ní ilé í wó,onílé ni kò ní gbà fun.
Ní òpin ọ̀ṣẹ̀ tó kọjá lọ yìí,ọpẹ́lọpẹ́ àwọn Àmọ̀tẹ́kùn tó fi ìbọn fọ́ táyà tírélà kan tó kẹ́ran-mérò tó kọ̀ láti dúró ní Ìlọràá lẹ́bàá Ọ̀yọ́, àwọn ènìyàn burúkú yìí kì bá tún kún àwọn tó ti wà nínú ìgbẹ́ wa síbẹ̀.
Nígbà tí wọ́n tù inú tírélà náà ni wọ́n rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ màálù, àwọn ènìyàn àti ìbọn lorisirisi
Àwọn mìíràn sá lọ sùgbọ́n ọwọ́ ba àwọn tí ó pọ̀ nínú wọn.
Ojú ni Alákàn fi ń sọ́rí ooo.ààbò ara ẹni ni ààbò ìlú óo.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
