Ìjọba Nàìjíríà yóò sinmi ẹ̀yáwó láti ilé òkèèrè…. Wálé Ẹdun

Mínísítà fún ìsúná àti Alàkóso ètò ọrọ̀ ajé ní ilẹ̀ wa Nàìjíríà, Ọ̀gbẹ́ni Wálé Ẹdun ti sàlàyé pé ilẹ̀ wa ti ṣetán báyìí láti tàkìtì ìpàkọ́ sí ẹ̀yáwó àyákúdórógbó.

Ìlú Washington DC ní orilẹ̀ èdè Améríkà ló ti fojú ọ̀rọ̀ yìí léde nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé ọdọọdún àwọn àjọ Ayánilówó àgbáyé nnì tí a mọ̀ sí IMF.

Ẹdun ni “Ó tó gẹ́ẹ́! alubàtá kìí dárin.Nàìjíríà náà ti gbáradì láti wá ojútùú sí ìsoro ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀ lábẹ́lé láìka ti kọ̀bàòle òhun àárẹ̀ tó ń fi ọjà èpo rọ̀bì lògbòlògbò sí “

Ẹdun ni orilẹ̀ èdè tó bá ń rá mùn-ùn nínú gbèsè jíjẹ kò ní le dide rárá.Láti lè dènà irúfẹ́ wàhálà báyìí ni Naijiria lábẹ́ Bọ́lá Tinúbú ti la orísìí òná àbáyọ láti pawó lábẹ́lé àti láti pọn omi sílẹ̀ de ôrùgbẹ sílẹ̀.

Lára àwọn ọ̀nà àbáyọ náà sì ní Títẹpá mọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ nípa ìpèsè ẹ̀yáwó àti ìfàyàbalẹ̀ fún àwọn àgbẹ lẹ́nu iṣẹ́ wọn .

Síṣe kóríyá fún àwọn Aládani ti wọn dá ilé iṣẹ́ ńláńlá àti okoòwò kéékèèké sílẹ̀.Gbígbájú mọ́ ètò àbò kó lè ro tótó sí i.Nípa sí ṣe eléyìí,ó dájú pé ilẹ̀ Nàìjíríà náà yóò lè fọwọ́ ṣọ̀yà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yíká àgbáyé.

Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn mínísítà ètò ìṣúná yíká àgbáyé àti àwọn onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ló péjú síbi ìpàde náà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×