Àgbàlagbà ni Ifeanyi Okowa àti Sheriff Oborevwori ,Wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tó bá wù wọ́n…. Atiku

Ìgbákejì Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP láàrin ọdún 1999 sí ọdún 2027, tíì tún ṣe olùdíje sí ipò Ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nínú ètò ìdìbò ọdún 2023, Atiku Abubakar tí ni mìmì kan kò mi òun nínú akitiyan òun láti fọwọ́ṣowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni ọ̀rọ̀ kàn láti lé ìjọba Bọ́lá Tinúbú kúrò ní orí àlèéfà lọ́dún 2027.

Lórí ìkànnì abẹ́yẹfò twitter rẹ̀ ló ti fojú ọ̀rọ̀ yìí léde lónìí òde yìí.

Ó ní ẹni tó díje pẹ̀lú òun lọ́dun 2023, ìyẹn Ifeanyi Okowa àti Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta Sheriff Oborevwori lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá wù wọ́n.

Atiku ni a lè fi tipátipá mú ẹṣin dé òdò ni,a kò lè fi tipátipá mú un mu ẹṣin.

Ìwọ̀nyii ni èsì ọ̀rọ̀ tí Atiku Abubakar fún lórí bí Ifeanyi Okowa àti Gómìnà Sheriff Oborevwori ṣe digbá-dẹrû wọn lọ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×