
Ìgbákejì Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí tii tún ṣe olùdíje sí ipò Ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nínú ètò ìdìbò ọdún 2023, Alhaji Atiku Abubakar ti fi léde pé kò sí láìfí nínú àbẹ̀wò tí òun àtàwọn Olóṣèlú kan ṣe sí Ààrẹ àná, Mohammed Buhari nílé rẹ̀ ní ìlú Kaduna lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.
Àtẹ̀jáde kan tí Atiku fọwọ́ sí tí wọ́n fi léde ní ìlú Abuja ni ọ̀rọ̀ náà ti jẹ jáde.
Atiku Abubakar ní kò sí èèwọ̀ nínú bí ènìyàn méjì tàbí mẹ́ta tí èrò wọn yapa nínú òṣèlú bá dìjọ jókòó,jẹun tàbí ṣe àjọṣe mìíràn papọ̀
Gẹ́gẹ́ bó ti wí, òsèlú kìí ṣe ìjà bí kò ṣe ìlàjà,kìí ṣe ikú bí kò ṣe ìyè.Bí a bá jà lónìí,a tún lè rẹ́ bó bá di ọ̀la.
Ó wá fi ti àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ olóṣèlú tí wọ́n ń fi ọ̀sán bá Tinúbú já ṣùgbọ́n tí wọ́n ń yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i lóru ṣe àpẹrẹ.
Ó wá ní ọ̀tá kan ṣoṣo tí gbogbo ọmọ Nàìjíríà ní ni ìṣèjọba Bọ́lá Tinúbú nítorí pé ó mú ayé le koko fún àwọn ènìyàn orilẹ ede yìí.
Turakin Adamawa wá ní wòhín-wọ̀hún a máa yín àgbà lọ́rùn, kí gbogbo tẹrú tọmọ Nàìjíríà gbájú mọ́ ọ̀nà àti ète tí ọwọ́ Tinubu kò fi ní tẹ ipò Ààrẹ lẹ́ẹ̀kejì.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
