Abẹ́ Wá Lẹ wà,Ẹ ò ní Òmìnira:Fásúà kìlọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Ìdàgbàsókè Agbègbè (LCDA)

Alága àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oǹdó, Họnọrébù Gbénga Fáṣúà ti kìlọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ ìdàgbàsókè agbègbè tí a mọ̀ sí Local Council Development Authority (LCDA) pé kí wọn yèé ṣe jù ara wọn lọ nípa dídá olú ilé iṣẹ ìjọba ìbílẹ̀ tí òfin mọ̀ kọjá lọ sí ìpínlẹ̀ tàbí ìjọba àpapọ̀.

Ìlú Àkúrẹ́ ni Fáṣúà ti sọ̀rọ̀ yìí nìgbà tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní ọọ́fíìsì rẹ̀.

Ó ní ó yẹ kí wọ́n ó mọ̀ pé ènìyàn ló ni Adimu,Adímu kó ló ni ara rẹ̀ àti pé orí ló ń bẹ ni àgbọ̀n fi ń mu omi.Ìjọba ìbílẹ̀ mejidinlogun ni òfin mọ̀ ní ìpínlẹ̀ Oǹdó amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ lásán ni àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀tàlélọ́gbọ̀n yòókù.

Fún ìdí èyí, kò yẹ kí olómele máa lérí-léka pé gudugbẹ̀ á já lóde láìkàn sí Onîyàáàlù.

Ó wá rọ̀ wọ́n láti ki ọwọ́ ọmọ wọn bọṣọ, kí wọ́n jáwọ́ lápọ̀n tí kò yọ̀, kí wọ́n dá omí ìlá kaná kí èkuru má baà ti ẹ̀yin ní ìfáǹfá mọ́ wọn lọ́wọ́.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×