Ọmọ ilé ìgbìmọ̀ Asojúṣòfin kan ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun;Wọlé Ọ̀kẹ́ ti fi ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP sílẹ̀.

Ògbóhùntarìgì Olóṣèlú kan tó tún jẹ́ ìtalẹ̀mú nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Họnọrèbù Wálé Ọ̀kẹ́ ti fi ẹgbẹ́ Òṣèlú náà sílẹ̀.

Eléyìí jẹyọ nínú lẹ́tà tó kọ sí Wọ́ọ̀dù keje ní ìjọba ìbílẹ̀ Obòkun ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Nínú lẹ́tà náà,Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú náà fún ànfàní tí wọ́n fún un ṣùgbọ́n òun ti ṣetán báyìí láti kúrò nínú ẹgbẹ́ náà Ó wá rọ àwọn ọmọlẹyìn rẹ̀ gbogbo láti kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní àdúgbò kóówá wọn kí wọ́n sì máa retí ìdarí láti ọ̀dọ̀ òun láìpẹ́.

Awon Òǹwòye ọ̀rọ̀ òsèlú kan wà ń sọ pé èdè àìyedè kan tó wà láàrin Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun àti Họnọrèbù náà ló fà á tó fi bínú kúrò nínú ẹgbẹ́ PDP.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn mìíràn ní kò sí ìjà láàrin òun àti Adélékè sùgbón ètò ìdìbò ọdún 2027 ló fa sábàbí ìgbésẹ̀ náà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×