Àwọn Alágbàtà epo Rọ̀bì banújẹ́ lórí ẹ̀dínwó epo bẹntiróòlù

Àwọn Alágbàtà epo rọ̀bì nílẹ̀ Nàìjíríà ti korò ojú sí bí owó epo ti já wálẹ̀ ní ọ̀ṣẹ̀ tó kọjá lọ.

Igbákejì alága ẹgbẹ́ náà lórílẹ̀ èdè yìí, Ọ̀gbẹ́ni Hammed Fáṣọlá ló fojú ọ̀rọ̀ yìí lede ní ìlú Èkó.

Gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, bí owó epo bẹǹtiróòlù ṣe já sí ọ̀rìnlélẹ́gbẹ̀rin náírà (#880 ) láti nǹkan bíi ọ̀rìndínlọ́gọ́rùn-un náírà (#920) náírà yóò kó gbèsè bá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn bí wọ́n bá ń ṣàdédé tà á bẹ́è.

Ó wá rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà kí wọ́n má ṣe bínú sí àwọn tí wọn kò bá tètè yí mítà wọn nítorí wọn fi ta èyí tó wà nínú kòtò tán ni.

Lórí ìbéèrè pé Ṣé ó ṣeéṣe kí epo bẹǹtiróòlù já wálẹ̀ sí bíi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà kí ọdún yìí tó parí , Hammed Fáṣọlá dákẹ́ láìfèsì kankan.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×