Tìlùtìfọn ni àwọn ará Arárọ̀mí Seaside fi kí Aiyédàtiwa àtaya rẹ̀ káàbọ̀ síbi ayẹyẹ àjọ̀dún Àjíǹde

Kò ní yẹni títí kí ilẹ̀ má ṣe ṣú.Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ rí fún gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó, Lucky Orímisàn Aiyédàtiwa àti ìyàwó rè,Olúwáṣeun lọ́jọ́ ajé ọjọ́ kọkànlélógún oṣù yìí ni Arárọ̀mí Seaside níbi tí àwọn olólùfẹ́ fàájì àti ìrìn àjò afẹ́ ti tẹ́ pẹpẹ fàájì fún pọ̀pọ̀ṣìṣìn ọdún àjíǹde.

Ohun tó tún mú kí ìdùnnú náà tún fa láńtà lọ́wọ́ ni rírí tí àwọn ènìyàn rí ìyàwó gómìnà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.

Nígbà tí Gómìnà ń kí àwọn ènìyàn tó wà níbi ayẹyẹ náà, Aiyédàtiwa ní ìgbáyégbádùn àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ Oǹdó ló jẹ òun lógún àti pé òun kò ní fojú rénà ìrìn àjò afẹ́ nínú ìṣèjọba òun.

Lára àwọn tó kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú Gómìnà ní alàkóso fún ètò ìdájọ́ àti Agbèfọ́ba àgbà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó, Amòfin àgbà Káyọ̀dé Àjùlọ àtàwọn lóókọlóókì mìíràn lẹ́nu iṣẹ̀ ọba.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×