
Ó dà bí ẹni pé òpin kò ì tíì dé bá ìjà tó ń bẹ láàrin Ọọ̀ni ilé ifẹ̀ Ọba Adéyẹyè Ògúnwùsì àti Olúwòó tí ilẹ̀ Ìwó,Ọba Abdulrasheed Adéwálé Àkànbí.
Ọ̀rọ̀ yìí fara hàn nínú ìfòròwánilénuwò orí fóònù tí Akínkúnmi Àlàbí ṣe pẹ̀lú Olúwòó lórí ẹ̀rọ rédíò Fresh fm, Òṣogbo láìpẹ́ yìí ní ìlú Òsogbo..
Lẹ́hìn tí Kábíyèsí dahùn òkan-o-jòkan ìbéèrè tó jẹ mọ́ àṣà àti ìṣe Yorùbá nínú èyí tí Olúwòó fi takú wọnnle pé ẹbọ síṣe àti òrìsà bíbọ kìí ṣe àṣà Yorúbá.
Ó ní asọ wíwọ̀ aṣọ, ìkíni àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ nìkan ni asa Yoruba.Lẹ́yìn èyí ló kí Aláàfin Ọ̀yọ́ titun àti àwọn ọba mìíràn tó fi dórí Sultan ìlú Sokoto ṣùgbọ́n kò kí Ọọ̀ni.
Bí Akínkúnmi Àlàbí ti ní kí ó kí Ọọ̀ni báyìí ni Olúwòó bá pa fóònù.Èyí túmọ̀ sí pé Kábíyèsí kò fi kí Ọọ̀ni ní.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
