Èèmọ̀ Wọ̀lú o! Wòlíì Obìnrin gba ọkọ ọmọ ìjọ rẹ̀.Ó ní Olúwa ló ní kí òun ṣe bẹ́ẹ̀.

Arábìnrin ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ ìyáàfin Njokwu ló ti ké gbàjarè lọ sórí ètò orí ẹ̀rọ rédíò kan tí a mọ̀ sí Hungry and Angry ní Liverpool ní ilẹ̀ England pe Wòlíì ìjọ tí òun ń lọ ,ìyẹn Wòlíì Bianchi, tí òun náà wá láti Nàìjíríà ti gba ọkọ òun.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe wí,ọkọ òun kò ṣe dáradára tó ní ilé, kò ṣe ẹ̀tọ́ fún ọmọ àti òun.ìdí rèé tí òun fi fi ọ̀rọ̀ lọ Ọ̀rẹ̀ òun kan,ẹni tó gba òun ní ìyànjú láti ti ẹsẹ̀ ilé bọ ọ̀rọ̀ náà nítorí irú ọ̀rọ̀ báyìí kìí ṣe ojú lásán.Òun yìí kan náà ló sì mú òun lọ sí ọ̀dọ̀ Wòlíì Bianchi,ẹni tó ní kí òun mú ọkọ òun wá.Òun sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé ọkọ òun yóò padà sí bó ti wà tẹ́lẹ̀.

Sí ìyàlẹ́nu òun, ní kété tí ọkọ òun àti  Wòli fi ojú kan ara wọn ni àrá ran bọ́m̀bù lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ òun fìdí pagbá sí ọ̀dọ̀ Wòlíì .Ṣé Jógíná la ní kò jó ire,Jògìnà tún wá gbè é lẹ́sẹ̀,ṣebi ọkọ òun kò wálé dáradára tẹ́lẹ̀ ní,ní báyìí, kò tilẹ̀ wálé rárá mọ́,ó tí dì bàbá Yáàdì, tí òun àti Wòlíì dìjọ ń ṣe Wọléwọ̀de.

Kàyéfì gbáà ni ọ̀rọ̀ náà jẹ́ fún Atọ́kún ètò Hungry and Angry.Kíá ló sì gbé fóònù tó pe Wòlíì tí a fẹ̀sùn kàn lórí ẹ̀rọ fóònù lọ́nà tó fún ìyáàfin Njokwu,Wòlíì àti Atọ́kùn ní ànfààní láti máa gbọ́ ara wọn ketekete.

Láìfòlòlò fọhùn, Wòlíì ní òdodo ni ọ̀rọ̀ náà àti pé Olúwa ló sọ pé kí òun gba ọkùnrin náà lọ́wọ́ rẹ̀ nitorí pé kadàrá wọn kò dọ́gba  ṣùgbọ́n kádàrá òun tí òun jẹ́ Wòlíì àti ọkọ rẹ̀ ló ṣe rẹ́gí jùlọ.

Ní ìdáhùn sí ìbéèrè pé ọgbọ́n wo ni àwọn lè ta tí yóò fi dá ọkọ ọlọ́kọ padà, Wòlíì ní ‘N kò lè tako ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run bá sọ.. Ṣùgbọ́n ní ó bá a wa ọkọ Alálùbáríkà mìíràn ‘

Èsì tí arábìnrin Wòlíì yi fọ̀ bí ìyáàfin Njokwu nínú ó ní ‘Ọkọ mi ni kò dá padà fún mi óò.Wòlii gbọkọgbọkọ.Ah! Ó ti fi òògùn mú ọkọ mi ni oo.N ó da ìjọ náà rú.’

Gbogbo akitiyan Atọ́kún  ètò láti parí ìjà náà ló já sí pàbó.Èyi ló sì fàá tó fi sún ìgbẹ́jọ́ síwájú lórí ọ̀rọ̀ náà.

L

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×