
Olórin ṣèwọ́ṣèwọ́ ọmọ Naijiria tó gba àmì ẹ̀yẹ Grammy nnì,Burna Boy ló tí fún Portable olórin ní ogún mílíọ̀nù náírà fún bí ó ti jáwé olúborí níbi ìdíje ẹ̀ṣẹ́ kíkàn fún àwọn olórin tó wáyé láàrín rẹ̀ àti Speed Darlington lópin ọ̀ṣẹ̀ yìí.
Tipátipá ni Darlington fi parí abala kìíní ìdíje náà nígbà tí ó ti fi ọwọ́ dá.Ìdí sí rèé tí kò fi lè tē síwájú nínú idije náà.
Nígbà tí ọ̀rọ̀ sì ti rí báyìí ni wọ́n fi kéde Portable gẹ́gẹ́ bíi eni tó jáwé Olúborí nínú ìdíje ẹ̀ṣẹ́ kíkàn náà.
Àṣeyọrí Portable yìí ló wú Burna Boy lórí tó fi fún un ní ẹ̀bùn owó tó tó ogún mílíọ̀nù náírà.
Nígbà tó ń dúpẹ́ lórí ẹ̀rọ Instagram rẹ̀, ọmọ Ọlálọmí ní ‘Náwónáwó yàtọ̀ sí ahun.Odogwu ni Burna Boy tẹ̀gàn kọ́.Ó ya mí níṣu tó gara’

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
