Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ṣe ìwọ́de tako ìjọba Donald Trump.Wọ́n ní ìjọba rẹ̀ ń ni àwọn lára

Ilẹ̀ Amẹrika ti sọ̀rọ̀ sókè tako gbogbo ìgbésẹ̀ ìjọba Donald Trump nípa síse ìwọ́de lọ́kan-ò-jọ̀kan káàkiri orílẹ̀-èdè náà.Wọ́n ní kò sí èyí tó mú ìdẹ̀rùn wá nínú gbogbo ìlànà ìjọba rẹ̀ láti ìgbà tí ó ti dé orí àlèéfà.

Ìpinnu àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì ni láti gùn lé ìwọ́de aláìnígbèdéke yíká gbogbo àràádọ́ta ìpínlẹ̀ tó ń bẹ ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

Lára àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣùn tí wọ́n fi kan Trump ni:Bíba ìlànà ìjọba tiwa-n-tiwa jẹ nípa àwọn ìgbésẹ tó mú kànánḿpá dání, Bíba ètò ẹ̀kọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga jẹ́ pẹ̀lú àwọn òfin tó ń lé àwọn àjòjì nílùú,Lílo agbára lọ́nà tí kò tọ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ

Árọ̀nì kò wálé, Oníkòyí kò sinmi ogun ni àwọn Olùfẹ̀hónú hàn náà ni àwọn yóò fi ọ̀rọ̀ náà ṣe.Wọ́n ní bi Ààrẹ Donald Trump kò bá wọ̀n ọ́n kún, àwọn náà kò ṣetán láti gbà á láàbọ̀.

Ọ̀kan lára àwọn Olùdarí ìwọ́de náà,Andy Parker ṣàlàyé pé àwọn ti ṣe ọgọ́rin ìwọ́de (80) yíká ìlẹ̀ náà.Orúkọ tí wọ́n sọ ìwọ́de náà ni 50501 tó túmọ̀ sí àádọ́ta ìwọ́de ní àádọta ìpínlẹ̀ láti ọwọ́ ìgbìmọ̀ kan ṣoṣo.

Ní Washington DC, àwọn ènìyàn ṣe ìwọ́de ni iwaju ilé igbakeji ààrẹ ilẹ̀ náà Ọ̀gbẹ́ni J.D Vance ẹni tó wà ní ilẹ̀ Róòmù lọ́wọ́lọ́ nígbà tí Ààrẹ Trump fúnra rẹ̀ wà ní ibùdó Gọ́ọ̀fù rẹ̀ tó wà ní Virginia .

Ìgbàgbọ́ ní pé Aare Donald Trump yóò yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ètò aninilára rẹ̀ padà lẹ́yìn iwode ọ̀hún.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×