Òfin Ṣẹ̀ríà Kò lè Ṣe Oore Kankan fún Ilẹ̀ Yorùbá.. Ààrẹ Ọ̀nà Kakaǹfò

Ààrẹ Ọ̀nà Kakaǹfò ilẹ̀ Yorùbá,iba Gàni Adams ti sọ pé ọgbọ́n àti ète àtida ilẹ̀ Yorùbá rú ni òfin Ṣẹ̀ríà tí àwọn kan ń pariwo pé àwọn ń fẹ ní àwọn ìpínlẹ̀ tó di ilẹ̀ Yorùbá mú.

Lóógunọfẹ se alaye ọ̀rọ̀ yìí lánàá ní ìlú Èkó nibi ìpàdé àpérò ti ẹgbẹ́ kan tí a mọ̀ sí Yoruba One Voice (YOV) tó ń pè fún òmìnira ilẹ̀ Yorùbá ṣe.

Adams ní ìṣọ̀kan àti ìtẹ̀síwájú ti ó jẹ ọba ní ilẹ̀ Yorùbá ló ń bí àwọn kan nínú ti wọ́n fi ń hun ète “Dà -bí -mo -ti -dà,ọlọ́kùnrùn tó ní omitoro ejò Abùrùṣoró ni òun fi jẹ” fún wa.Nítorí kò sí ilú ti ofin Ṣẹ̀ríà wọ̀ tí kìí bàjẹ́.

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nibi ìpàdé àpérò náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Olùwafẹ́mi Ọbáyọrí kín ọ̀rọ̀ iba Gàni Adams lẹ́yìn nípa wíwọ inú àká ìtàn níbi tó ti ṣe àlàyé pé ẹ̀sìn Mùsùlùmí ti pẹ́ tó ọ̀pẹ àgogo ní ilẹ̀ Yorùbá tó sì wà ní irẹ́pọ̀ pẹ̀lú tẹrútọmọ, láìsí o-gbún-mi-o-tẹ̀-mí.Kò wá yẹ ká rójú tán, kí á máa tanná wá àìrójú kiri nipasẹ Sẹ̀ríà.

Nínú ọ̀rọ̀ tirè, Ọ̀jọ̀gbọ́n Kọ́láwọlé Raheem ní bí òfin Sẹ̀ríà bá máa wà ní ilẹ̀ Yorùbá, kó jẹ́ fún àwọn ẹlẹ́ṣìn mùsùlùmí nìkàn láìdúnkookò mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣìn mìíràn bíi ti òkè-ọya.

Fún udu

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×