A ní láti tún ètò ẹ̀kọ́ wa sọ bí ẹni sọ igbá ní Nàìjíríà … Àlàbí

Igi ìwé,gbòǹgbò ìmọ̀ kan tíí tún ṣe ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ nípa ààtò ẹ̀kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga jùlọ Yunifásítì Adékúnlé Ajáṣin tó wà ní ìlú Àkùngbá Àkókó, Ọ̀jọ̀gbọ́n Festus Olúwọlé Àlàbí ti sọ yanya pé ọ̀pọ̀ èpò ni kò jẹ́ kí Àlìkámọ̀ ètò ẹ̀kọ́ ó dágbà ní Nàìjíríà.

Òjìnmì onímọ̀ yìí sàlàyé ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń ka àpilẹ̀kọ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nibi ìdànilẹ́kọ̀ọ́ ìfinimawo sí ipò ọ̀jọ̀gbọ́n ẹlẹ́ẹ̀kẹtàdínlọ́gbọ̀n rẹ̀ tó wáyé ní gbọ̀ngàn ńlá ti ilé ìwé gíga julọ náà ní ọjọ́ ìṣẹ́gun ọ̀sẹ̀ yìí.

Àlàbí ní bí a sè dá ilé ayé ní tibitire náà la dá àwọn èèyàn ibí àti ire sí agbọn ètò ẹ̀kọ́.Ṣugbọ́n ohun tó burú jùlọ ni pé àwọn paramọ́lẹ̀ ẹ̀dá ló pọ̀ jù nínú ìsàkóso àti ààtò ẹ̀kọ́ ní Nàìjíríà.

Ìdí si rèé ti ètò ẹ̀kọ́ wa fi ń rá bójó lójú kan, tó sì ń fi ẹ̀yìn rìn bíi ọ̀fàfà.Ó wá pè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàrin àwọn Lámèétọ́ ètò ẹ̀kọ́ láti fi ìgbánú kan ṣoṣo ṣe ọ̀já lójúnà àti tún ètò ẹ̀kọ́ wa rọ ní ilẹ̀ Nàìjíríà.

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ náà, Gííwá ilé ẹ̀kọ́ gíga jùlọ Yunifásítì Adékúnlé Ajáṣin, Ọ̀jọ̀gbọ́n Olúgbénga Ìgè kan ṣáárá sí Ọ̀jọ̀gbọ́n Àlàbí fún bó ṣe wú ìṣòro tó ń dààmú ètò ẹ̀kọ́ wa tigbòǹgbòtigbòǹgbò pẹ̀lú ọ̀nà àtiwá ojútùú sí ìṣòró náà bó ti jẹyọ nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún.

Gííwá wá rọ àwọn tí ẹnu wọ́n tó ọ̀rọ̀ láwùjọ láti ṣe àmúlò àpilẹ̀kọ náà fún ọjọ́ ọ̀la tó jíire fún ètò ẹ̀kọ́ ilẹ̀ wa Nàìjíríà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×