
Ìyàwó Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà,Sẹ́nétọ̀ Olúrẹ̀mí Tinúbú ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò Ìrètí ọ̀tun tòhún ti àtinúdá(Renew hope initiative). lónì-ín ní Gbọ̀ngàn ayẹyẹ ńlá ti DOME tó wà ní ìlú Àkúrẹ́ ti ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Oǹdó.
Nibi ayẹyẹ náà ni Sẹ́nétọ̀ Olúrẹ̀mí Tinúbú ti kéde òhun èlò ìlera tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá fún àwọn Nọ́ọ̀sì àti Agbẹ̀bí ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà.
Gẹ́gẹ́ bó ti wí, irufẹ ìfilọ́lẹ̀ yìí ti wáyé ní gbogbo ẹkùn yíká orile-ede wa ṣùgbọ́n eégún ńlá tó ń gbẹ̀yìn ní ìgbàlẹ̀ ni àwọn fi ìfilọ́lẹ̀ ti Àkúrẹ́ yìí ṣe.
Ó wá gbé àádọ́ta mílíọ̀nù náírà kalẹ̀ fún Olúwáṣeun Aiyédàtiwa tii ṣe ìyàwó gómìnà ipinlẹ Oǹdó láti máa lò bíi ohun ìrónilágbára fún àwọn obìnrin ní ìpínlẹ̀ yìí.

Nígbà tó ń dúpẹ́ lórúko àwọn obìnrin ipinlẹ̀ Oǹdó, Arábìnrin Aiyédàtiwa kókè Sẹ́nétọ̀ Olúrẹ̀mí Tinúbú eni tó ṣe àpèjúwe rè gẹ́gẹ́ bí abiamọ tòótọ tí kìí jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìpínlẹ̀ Oǹdó ṣú òun.Ó wá jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ríi dájú pé gbogbo agbára tó bá wà ní ìkáwọ́ òun ni òun yóò lò láti mú àwọn obìnrin ìpínlẹ̀ Oǹdó kúrò nínú òsì .

Saájú ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó, Lucky Aiyédàtiwa ti yòǹbó ìjọba àpapọ lábẹ́ ìsàkóso Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú fún àwọn àkànṣe iṣẹ́ ọlọ́kan-ò-jọ̀kan ti ìjọba náà ti ṣe ní ìpínlẹ̀ Oǹdó.

Lára àwọn iṣẹ́ náà ni sísọ Adéyẹmí College of Education, Oǹdó di Yunifásítì,Dídá ilé ẹ̀kọ́ girama àwọn ọmọ ogun òfurufú sílẹ̀ ní Ìgbàrà òkè, ìdásílẹ̀ ilé ìwòsan ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìṣègùn ti FUTA,Sísọ ọ̀nà Ọ̀rẹ̀ sí Àkúrẹ́ di oníbejì àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Ó tún wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Arábìnrin Tinúbú fún bó ṣe yan ipinlẹ Oǹdó láàyò gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n yóò ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìrètí ọ̀tun tòhun ti àtinúdá (,Renew Hope Initiative).
Ó wá sàlàyé pé ìjọba òun kò kó iyán àwọn obìnrin kéré nínú ètò ìṣèjọba àti ìyannisípò.

Àwọn ẹgbẹ́ obìnrin lẹ́lẹ́kaǹka, àwọn ọ̀tọ́kúùlú gbogbo ló péjú síbi ayẹyẹ náà.Àwọn aláré ìbílẹ̀ ti ilé iṣẹ́ àṣà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó jó àjótàpá láti mú kí ayẹyẹ náà dùn.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
