
Ọba orin fújì tíí tún ṣe ọ̀jọ̀gbọ́n alátinúdá tó máa ń rọ orin bí ìgbà tí alágbẹ̀dẹ bá ń rọ àdá nnì, Saheed Akóredé ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Saheed Òṣùpá ti fagi lé ẹjọ́ ìbanilórúkọjẹ́ àti ìjínilórinlò tó fi kan Olórin Ṣèwọ́ṣèwọ́ tí ẹnu kìí ṣìn lára rẹ̀ bii Afọ́ìkéèmù nnì, Habeeb Òkìkìọlá Ọlálọmí ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Pọ́tébù.
Àtẹ̀jáde kan ti olùbádámọ̀ràn pàtàkì rẹ̀,Busari Basit fọ́wọ́ sí ní ìrọ̀lẹ́ òní ọjọ́ ìṣẹ́gun ọjọ́ kéẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹrin ọdún yìí ló fi ọ̀rọ̀ náà tóni létí.
Saheed Òṣùpá ní kí èrà má fini pe Igi la ṣe ń wọ́n ọn àti pé bí a kò bá pa ìjí han ìjí,ẹ̀rù kò ní ba ọmọ Ìjímèrè.
Ó wá gba Pọ́tébù ní ìmọràn láti yèé hùwà bíi ọmọ gànfé nítorí iṣẹ́ iyì òhun ẹ̀yẹ ni iṣẹ́ tó gbé dání.
Bí a bá yin ọdẹ,ó yẹ ká yin apó; bí a bá yin apó, ó yẹ ká yin ọfà;, bí a bá wá yin ọfà tán, ká mọ sàìyin ojú tó sin ọfà dé ọ̀dọ́ ẹran tí oró fi mú ẹran.
Ìdí rèé tí ọba orin fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn bí ènìyàn ti wọ́n dá sí ọ̀rọ̀ náà.Lára wọn ni Alhaji Ahmed Lawal, aláṣẹ àti olùdarí ilé iṣẹ́ Lahmad Concepts.Saheed Ìbílẹ̀,Fàtáì Lájerò , gbogbo olólùfẹ́ rẹ̀ káàkiri àgbáyé àti gbogbo ìlú Nàìjíríà lápapọ̀.
Ó wá ní kí ọ̀rọ̀ náà lè kú rewé-regbò, kí Amòfin tó ń gba ẹjọ́ rò fún Pọ́tébù, Olóyè Isaac Adébáyọ̀ fi ẹnu ara rẹ̀ sọ pé irọ́ ni ọ̀rọ̀ tí òun sọ pé Pọ́tébù ń dọ̀bálẹ̀ bẹ òun lórí ọ̀rọ̀ ayélujára.
Ó ní ó dun òun pé àgbàlagbà agbẹjọ́rò bíi irú olóyè Isaac Adébáyọ̀ lè máa pa irú irọ́ àfohùnfojúrí bẹ́ẹ̀.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
