
Ìgbìmọ̀ Aṣàkóso ilé ẹ̀kọ́ gíga jùlọ Yunifásítì ìjọba Àpapọ̀ tó wà ní ìlú Ọyẹ́-Èkìtì ní ìpínlẹ̀ Èkìtì ti pàṣẹ fún gííwá ilé ìwé náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Àbáyọ̀mí Sunday Fásínà kó lọ rọọ́kún nílé ná ṣùgbọ́n ó bẹ̀bẹ̀ kí wọ́n jẹ́ kí òun lọ lo àjẹẹ́lẹ̀ ìsinmi òun, eléyìí tí ìgbìmọ̀ náà sì gbà fún ùn kó ṣe bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹrin ọdún yìí
Ìgbìmọ̀ náà sì ti yan igbákejì rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Samuel Shittu gẹ́gẹ́ bíi Adelé Gííwá fún oṣù mẹ́fà àkọ́kọ́.
Bí kò bá ní ìdí, obinrin kìí jẹ́ Kúmólú.Ọ̀gá àgbà kan ní ilé ẹ̀kọ́ gíga náà,Onímọ̀ ẹ̀rọ Fọláṣadé Adébáyọ̀ ló ké gbàjarè síta pé Gííwá fẹ́ fi tipátipá jẹ ẹran súnkunsí lára òun.Ó ní ọ̀wẹ̀ ni òun pe ọ̀rọ̀ náà àfi ìgbà tí ó ń ní Àáró nínú ni òun fi sọ̀rọ̀ síta.
Ní kíá sì ni àwọn ìgbìmọ̀ tí Sẹ́nétọ̀ Victor Ndume Egba kó ṣòdí ti jókòó lórí ọ̀rọ̀ náà tí wọ́n sì ni kí Fọláṣadé tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ ọ̀gá ẹ̀.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Fásínà rò pé òun ti fí ọ̀rọ̀ náà fín tábà ni,àfi ìgbà tí èkuru ọ̀rọ̀ náà tẹ̀yìn ní ìfáǹfá, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fa ìbínú yọ lápò Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Túnjí Aláhúsá; eléyìí tó mú pàṣẹ àtúnjókòó ìgbìmọ̀ náà tó bí bí wọ́n ṣe ní kí Gííwá lọ sinmi díẹ̀ ná.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ní wọ́n wá ti pé fún ìwádìí tó lọ́ọ̀rìn lórí ẹ̀ṣùn náà

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
