Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Ṣetán láti ran KAP lọ́wọ́…Mákindé

Gómìnà Ṣèyí Mákindé

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ́yọ́,Onímọ̀ ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé ti jẹ́jẹ̀ẹ́ àtìlẹ́yìn tó gbọ́nngbọ́n fún ilé iṣẹ́ KAP FILM VILLAGE AND RESORTS tó wà ní Igbójàyè ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ ìtèsíwájú ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ọjọ́ Àbámẹ́ta ọjọ́ kejìlá oṣù yìí ni Mákindé jẹ́jẹ̀ẹ́ yìí níbi ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ Abúlé Eré ìtàgé àti ibi ìgbafẹ́ tí a mọ̀ sí KAP film Village and Resort Centre, tí Ògbóhùntarìgì Onísinimá nnì,Kúnlé Afọláyan dá sílẹ̀.

Gómìnà ní inú òun dùn pé Kúnlé Afọláyan tí kìí ṣe ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ronú kan ipínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti jẹ́ alábàápín nínú ìlàkàkà rẹ̀ láti mú kí àṣà àti ìṣe Yorùbá di Àpèwáàwò yíká àgbáyé.

Mákindé ni ‘Ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bí ìjọba ni láti pèsè àyíká tí yóò mú kí ó rọrùn àwọn aládàáni láti lè máa dá iṣẹ́ sílẹ̀’ Gómìnà wá ní òun yóò fa iná ìjọba àtí ti ìtànsán òòrùn tí a mọ̀ sí Solar light sí ibùdó náà.

Ní ìtẹ̀síwájú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ṣèyí Mákindé ní òun tí pàṣẹ fún alága ìjọba ìbílẹ̀ Ìtèsíwájú láti pèsè ọ̀nà fún ilé iṣẹ́ náà.

Mínísítà fún ọ̀rọ̀ àṣà àti ìrìnàjò afẹ́ ní Nàìjíríà, Hanatu Musawa náà wá jẹ́jẹ̀ẹ́ àtìlẹ́yìn ìjọba Àpapọ̀ fún ibùdó náà.Bákan náà ló ṣe sámọ́ńsáńgúdù sí Afọláyan fún ipa tó ń kó lórí ìdàgbàsókè àṣà àti ìrìnàjò afẹ́ ní Nàìjíríà.

Nígbà tó ń fèsì,Kúnlé Afọláyan ní àtúnṣe àti igbélékè èdè àti àṣà Yorúbá ló ta òun nídìí kán láti ṣe ìdásílẹ̀ ibùdó náà.

Ó ní ibùdó náà yóò mú kí sinimá síṣe ó dìrọ̀rùn fún àwọn onifiimù.Yàtọ̀ sí èyí, àwọn tí wọ́n ní ìfé sí ìrìnàjò afẹ́ náà lẹ́tọ̀ọ́ sí ibè.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ńláńlá ló péjú-pésẹ̀ síbi ayẹyẹ náà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×