Bísọ́ọ̀bú Bọ̀rọ̀kìnní ṣe ayẹyẹ ogójì ọdún nínú ìgbéyàwó;Àkúrẹ́ mì tìtì!

Òní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹrin ọdún 2025 ló pé ogójì ọdún tí Bísọ́ọ̀bù ilẹ̀ Àkúrẹ́ tii tún ṣe Bíṣọ́ọ̀bù Aláṣẹ àgbà fún ẹkùn Oǹdó, Àlùfáà jùlọ Simeon Olúwọlé Bọ̀rọ̀kìnní àti ìyàwó re Ọmọọbabìnrin Christiana Adétúnbí Bọ̀rọ̀kìnní ṣe ìgbéyàwó.

Ìjọ Maria Wúndíá mímọ́ tó wà ní Alágbàká ní ìlú Àkúrẹ́ kò gba ẹsẹ̀ fún àwọn òbítíbitì èrò tó wà bá wọn yọ ayọ̀ àṣeyọrí ìgbéyàwó aláìlábàwọ́n náà.

Nígbà tó ń wàásù níbi ayẹyẹ náà,Bísọ́bù àgbà ìjọ Anglican ẹkùn ti ilẹ̀ olúji,Àlùfáà àgbà Abel Ajíbódù gba ìdílé Bísọ́bù àgbà Bọ̀rọ̀kìnní àti gbogbo àwọn lọ́kọláya níyànjú láti má ṣe fi agogo alágogo ṣe iṣẹ́.Ó wá gbàdúrà fún wọn pé pípẹ́ lowú ń ṣe ilé arọ́, wọn kò ní kánjú kú lágbára Olúwa Elédùmarè.

Nínú ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ rẹ̀,Bísọ́bù Olúwọlé Bọ̀rọ̀kìnní dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn gbogbo tó péjú-pésẹ̀ síbi ayẹyẹ náà.Wọ́n gbàdúrà pé ire á kárí.

Akọ̀we ìjọba ìpínlẹ̀ Oǹdó, Ọ̀gbẹ́ni Táíwò Fásọ̀ràntì ló ṣojú Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó, Họnọrèbù Lucky Aiyédàtiwa níbi ayẹyẹ náà.

Lára àwọn ènìyàn ńláńla tó péjú-pésẹ̀ síbi ayẹyẹ náà ni olùdíje sí ipo Gómìnà lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nígbà kan rí, Olóyè Èyítáyọ̀ Jẹ́gẹ́dẹ́, Agbèfọ́ba àgbà àti kọmísánnà fún ètò ìdájọ́ ní ìpínlẹ̀ Oǹdó,Amòfin àgbà Káyọ̀dé Àjùlọ,Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Oǹdó, Ọ̀gbẹ́ni Adé Adétìmẹhìn,Kọmísánnà àná fún ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin ní ìpínlẹ̀ yìí,Díákónì obìnrin Lọlá Fágbèmí àtàwọn lóókọlóókì mìíràn láwùjọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×