Mo ṣetán láti ṣe ìyàwó Kẹfà…Tókè Mákinwá

Ògbóhùntarìgì oníṣẹ́ orí afẹ́fẹ́ kan, Omidan Tókèr Mákinwá ti sàlàyé pé òun kò kọ àjẹkù níbi tí òun bá ọ̀rọ̀ ilé ayé òun dé báyìí.Ó ní kódà, bí a bá rí ọkùnrin tó ṣetán láti fẹ òun ṣe ìkejì, ìkẹta kódà bó ṣe íkẹfà, òun ṣetán láti bá mọ́ ẹní bẹ́è.

Lórí ọ̀kan lára àwọn ètò rẹ̀ ló ti sọ bẹ́ẹ̀.O ní kìíṣe àìníyàwó nìkan ni kò ṣe í dákẹ́ sí,àìlọ́kọ́ náà kò ṣe í dákẹ́ sí.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe wí, kò dára kí ènìyàn dàgbà tó ẹni ogójì ọdun bí toun yìí laini ọkọ àti ọmọ .

Tókè ní ẹkún abẹ́ aṣọ gbáà ni òun ń ṣun, kí Olúwa rẹ òun lẹ́kun ni.
Ní ọdún 2017,ní ìgbéyàwó Tókè túká.Láti ìgbà náà sì ni ó tí wà ní òun nìkan

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×