
Akọ́nimọ̀ọ́gbá ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Super Eagles tẹ́lẹ̀, Christian Chukwu ti di olóògbé ní ẹni ọdún merinléláàádọ́rin (74 yrs)
Òwúrọ̀ àná ni àkùkọ kọ lẹ́yìn Àgbà ọ̀jẹ̀ Akọ́nimọ̀ọ́gbá àti Agbábọ́ọ̀lù náà.
Ti a kò bá gbàgbé, Christian Chukwu, Emmanuel Okala,Sẹ́gun Ọdẹ́gbàmí àti àwọn èèkàn agbábọ́ọ̀lù mìíràn ni wọ́n dìjọ ṣe iṣẹ́ pọ̀ gba ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ fún ilẹ̀ Nàìjíríà ní ọdún 1980.
Ní ọdún 2021 ni òkìkí kọ́kọ́ kàn káàkiri pe Christian Chukwu kú.Nígbà tó di ọjọ́ kẹrin oṣù kínní ọdún 2021 ló sọ nígbà tó ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ààdọ́rin ọdún rẹ̀ pé irọ́ ni sùnmọ̀mí tí àwọn kan ń gbé kiri pé òun ti kú.
Ìtàn kò ní gbàgbé Christian Chukwu tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ń pè ní Chairman fún ipa tó kó fún ìdàgbàsókè eré ìdárayá lápapọ̀ àti eré bọ́ọ̀lù ní pàtó yíká ìlẹ̀ Nàìjíríà

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
