Ní Kwara, Ará Ọ̀run Ló síwájú Ìfẹ̀hónú hàn

Àrà méríìírí ni ìwọ́de tako owó gege tó gun owó iná mọ̀nàmọ́ná ní ìlú Òmù Àrán tó wà ní ìpínlẹ̀ Kwara lópin ọ̀ṣẹ̀ yìí nibi tí Àwọn Ará Ọ̀run kìnkinkìn méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti léwájú ìfèhónú hàn tí àwọn ará ayé sì ń wọ́ tẹ̀le lẹ́yin gẹẹrẹgẹ bí ìgbà tí àgbẹ̀ bá ń wọ́ tọ ọkọ́ rẹ̀ lẹ́yìn.

Kókó ohun tó gbé ará ọ̀run wá ṣáyé ni láti wá jáwé akìwọwọ fún àjọ Apínnáká IBEDC kí wọ́n dá owó ti àwọn oníbàárà wọn ń sán padà sí bó ti wà tẹ́lẹ́ nígbà tí wọ́n wà ní ipín B àti C ti wọ́n ń san bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lóṣù yàtọ̀ sí ìpín A tí wọ́n ti ń san bíi ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì tó wà bayii.

Lára ohun tó wà lára òkan-o-jòkan pátákó ajuwe tí wọ́n gbé lọ́wọ́ ni:Òmù àrán ti sọ̀rọ̀ sókè, A ò fún ìpín A,Ẹ dá wa padà síbi tí a wà tẹ́lẹ̀.àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìwọ́de náà gbé wọn yíká ìlú dé àwọn agbègbè bíi:Ọjà Olómù,ọjà Látińwọ́,ọọ́fíìsì àjọ Apínnáká IBEDC tó wà ní Òmù àrán City Complex àti ààfin Olómù.

Àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà pagi dínà ìgbòkègbodò ọkọ̀ láàrin ìlú náà nítorí wọ́n dí àwọn ọ̀nà tó lọ sí Kabba,Ọ̀tun Èkìtì àtàwọn ọ̀nà mìíràn tó wọ ìlú náà pinpinpin.

Àtẹ̀jáde kan tí Alága ẹgbẹ́ Ìdàgbàsókè ìlú Òmù àrán(OPU) , Ọ̀gbẹ́ni Níyì Adéyẹyè fọwọ́ sí ṣàlàyé pé Àrọ̀nì kò wálé, Oníkòyí kò sinmi ogun ni ọ̀rọ̀ náà.Ó ní àwọn kò ní yé fi ẹ̀hónù hàn tako àjọ IBEDC titi tí wọn yóò fi dáhùn ìbéèrè àwọn bíi: Títún àwọn ẹ̀rọ amúnáwá tó ti bàjẹ́ ṣe,Dídá Òmù àrán padà sí ìpín B àtí C tí wọ́n wà têlẹ̀ ,kí wọ́n jí gìrì sí ojúṣe wọn nipasẹ ríra òpó iná àti àwọn ohun mìíràn tó bá bàjẹ́ fúnra wọn dipò kí ará ìlú máa rà wọ́n kí wọ́n sì tún máa gba owó lori rẹ̀ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Ààfin Olómù ni wọ́n parí ìfẹ̀hónúhàn náà sí.Nígbà tó ń kí wọn kú ọmọ Akin í ṣe,Olómù tí Òmù Àrán,Ọba Abdulraheem Adéòtí kí wọn kú ẹ̀tọ́ ìlú, ó wá rọ̀ wọ́n kí wọ́n ṣe sùúrù nítorí ẹ̀kọ gbígbóná ń fẹ́ sùúrù àti pé ohun àfẹ̀ṣọ̀mú kìí bàjẹ́, ohun afagbára mú ló ń nini lára kokoko.

Kábíyèsí wá fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn pé àjọ IBEDC yóò wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi sàdá lórí àwọn ìbéèrè wọn.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×