
- Bí òtítọ́ bá wà nínú ọ̀rọ̀ tí Arábìnrin tó wà nínú fọ́tò òkè yìí sọ nínú ìjẹ́rìí rẹ̀ nínú ìjọ Chosen Charismatic Church káàkiri àgbáyé,èks ti ìlú Èko lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, a jẹ́ pé gbogbo ọmọ ìjọ náà kò nílò láti máa ka ìwé kí wọ́n tó yege nínú ìdánwò.
- Gẹ́gẹ́ bí Obìnrín náà ṣe wí “Ìdánwò ìgbéga ìjọba àpapọ̀ tó jẹ́ tí àwọn ọmọ olóógun ní a ń ṣe, Àádọ́ta ni àpapọ̀ àwọn ìbéèrè tí wọ́n fún wa.Ogójì nínú ìbéèrè náà ló jẹ mọ́ iṣẹ wa nígbà tí ìbéèrè mẹ́wàá yòókù ní í ṣe pẹ̀lú Ọ̀rọ̀tóńlọ.
- Ní agbọn Ọ̀rọ̀tóńlọ yìí ni wón ti ní ká dárúkọ àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́wàá tí ìjọba ilé Faransé mú ṣìn ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.Wàhálà ńlá lèyí jẹ́ fún mi nitori n kò mọ̀ ọ́n.Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn náà ní kò mọ̀ ọ́n.Lójú kan náà ni mo na ìwé ìbéèrè mí sókè tí mo ṣì gbàdúrà bayii ‘Ọlọ́run ìpè Bàbá mi Chosen,n ò gbọdọ̀ ṣe àsetì’ Kí n tó dákẹ́ ni bàbá Àgbà kan tí ó wọ aṣọ funfun bá wọlé wá,Ó dúró tì mí,Ó sì ń pè èsì awọn ìbéèrè náà fún mi.
- Awọn Alámòjútó wa fura,wọ́n ni kí n bọ́ aṣọ ìlékè mi.Wọ́n rò pé ibè ní mo ti ń jíi kọ.Bí wọ́n ti gba aṣọ lọ́rùn mi ni bàbá pòórá.Láìfa ọ̀rọ̀ gùn,wọ́n dá aṣọ padà fún mi.Bi wón ti da aṣọ padà fún mi ni bàbá tún dé tí mo ṣì pari isẹ náà ni kiakia.
- Kódà,mo fi èsì náà han awọn ènìyàn tó sún mọ́ mi.Ẹ bá mi yin Olúwa lógo.”Bí ó ti parí ijẹ́rii ni ariwo ijó àti ayọ̀ gba ìjọ kan.
- Nígbà tí ó ń fèsì lórí òrò náà.Alága Àjọ Onígbàgbọ́ iyen CAN ní ìpínlẹ̀ Èkó,Biṣọ́ọ̀bù Stephen Adégbìtẹ́ kọminú lórí àwọn òkan-o-jòkan àgbélẹ̀he ìjẹ́rii to máa n ti ọpọlọpọ awọn ile ijọsin wá.O wá ni àjọ náà yóò ṣe ìpàdé lórí ọrọ náà nínú ọ̀sẹ̀ tó n bọ̀.Ó ní Ọlọ́run kìí ṣe àyídàyidà, bẹ́ẹ̀ ni Kò nífẹ̀ẹ́ sí màgòmágó ìdánwò.
- Alukoro ìjó náà,Pásítọ̀ Chidi Louis ni àwọn ènìyàn ní wọn ti fi tiwọn kun fídíò náà nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ ojú àlá lásán ni.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!

Smile ☺, this is fantastic