Ibrahim Chatta fi ẹṣin ta Aláàfin lọ́rẹ

Ìlúmọ̀ọ́ká onítíátà tó dá abúlé eré ìtàgé aládàáni sílẹ̀ ní Nàìjíríà nnì, Ibrahim Chatta ti ṣe ohun kàyééfì ńlá ní bó ti fi ẹṣin ńlá rọ̀gbọ̀dọ̀ ta Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́,ọba Hakeem Ọ̀wọ́adé lọ́rẹ.

Ṣé ibi gẹrẹyẹ làá bá àgbà,Ààfin ọba tó wà ní Àkẹ̀sán ní àárín gbùngbùn ilú Ọ̀yọ́ ni àgbà Òṣèré náà ru ohun-àgùn-ṣawo náà lò bá baba.

Bí aláro ti ń lu aro,ni oníṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ń mi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ti onílù sì ń ṣẹ̀.Gbogbo ààfin ní pàtó àti ìlú Ọ̀yọ́ lápapọ̀ wá ń mì tìtì .

Kò sí eléré orí ìtàgé tàbí òǹkọrin tó ta ọba kankan ní irú ọrẹ báyìí rí ní ilẹ̀ Yorùbá .Múwá múwá ni ilẹ̀kùn àwọn òṣeré máa ń dún;Ìlẹ̀kùn wọn kìí dún Gbàgbà rí, ṣùgbọ́n Ibrahim Chatta ti sọ eléré ní súúná rere báyìí

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×