
Òdodo ni ọ̀rọ̀ àwọn àgbàlagbà tó sọ pé Aburú àti Ire dìjọ ń rìn ni àti pé ìbànújẹ òhun ayọ̀ kò jinná sí ara wọn.Ọ̀rọ̀ yìí ló wà ní ìbámu pẹlú bí ayọ̀ ọkọ ìyàwó kan ní Kano ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abdullahi Musa Hussein ṣe pàdé ìbànújẹ́ lọ́nà: Ó rí ẹ̀wọ̀n he,Ó sì ti inú òmìnira bọ́ sí inú ìdè .
Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní pé àjọ EFCC ló fi páńpẹ́ ọba gbé Hussein látàri pé o fí ojú owó náírà ilẹ̀ wa rí rẹ́dẹrẹ̀dẹ ,ó fi àbùkù kàn án,ó yẹ̀yẹ̀ rẹ̀ pèlú nígbà tí ó ń jó ní gbọ̀ngàn ayẹyẹ Ali Jita Every Centre tó wà ní ìlú Kano ní ọjọ́ kẹfà oṣù Kejìlá ọdún 2024.
Nígbà tó ń rojọ́ nínú Kóòtù, aṣojú ìjọba,Zarami Mohammed ní Hussein ṣe owó tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún náírà báṣubàṣu eléyìí tó tako abala kọkàndínlógún òfin Báǹkì àpapọ̀ ilẹ̀ wa, eléyìí tí ìjìyà tó dógbin sì wà fún.
Adájọ́ S.M Shuaibu wá bi í léèrè bóyá ó jẹ̀bi tàbí kò jẹ̀bi.Kíá ni òun náà sì ti gbà pé òun jẹ̀bi .
Ìdí rèé ti Adájọ Shuaibu fi rán an ní ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà láìsí ànfàní láti san owó ìtanràn.
Bí a kò bá ní gbàgbé, àwọn ènìyàn ńláńla náà ti káwọ́ pànyìn rojọ́ lórí ẹ̀ṣùn ìmẹ́ẹ́rí owó náírà.Lára wọ́n ni Bobrisky,Cubana chief Priest,Simi Gold àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
