……ìfẹ̀hónú hàn gbòdé ní Àkúrẹ́
……Wọ́n gbé òkú àwọn tí wọ́n pa lọ sí ẹnu ọ̀nà ọọ́fíìsì Gómìnà
Ìbànújẹ dórí àgbà kodò lọ́jọ́ ìṣẹ́gun àná nitori làlúrí tó mú ẹ̀mí àwọn àgbẹ̀ bíi mẹ́rin lọ ní agbègbè Tafa,Àjàgbusì tí gbogbo wọn wà ní òpópónà Ìgbátòrò ní ìlú Àkúrẹ́.

Gẹ́gẹ́ bíi ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, àwọn Fúlàní darandaran ni wọ́n yìnbọn pa àwọn àgbẹ̀ náà nígbà tí wọ́n ń tí oko wọn bọ̀.
Ìṣẹ̀lẹ̀ náà bí àwọn ará abà náà nínú tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi gbé òkú àwọn ènìyàn náà wá sí ẹnu ọ̀nà ọọ́fíìsì Gómìnà kó lè fi ojú ara rẹ̀ rí.
Ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn àwọn Fúlàní darandaran ti di tọ́rọ́fọ́nkálé ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ìlà oòrùn Àkúrẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi dín ní ọgbọ̀n ènìyàn tí àwọn darandaran ti ṣe ẹ̀mí rẹ̀ lófò ti wón sì ti sọ ẹgbàágbèje dì aláìnílé.
Ọ̀kan lára àwọn Afẹ̀hónú hàn náà sàlàyé pé ìjọba ìpínlẹ̀ Oǹdó kò ka ìgbáyégbádùn ọmọnìyàn sí rárá.Ó wá ní nǹkan kò rí báyìí nígbà ayé Gómìnà Rótìmí Akérédolú.
Ó wá rọ ìjọba láti jí gìrì sí ojúṣe rẹ̀ nípa pípèṣè ààbò tó nípọn fún àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ yìí.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
