
Ògbóhuntarìgì Olóṣèlú kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asojú-ṣòfin , Họnọrèbù Nicholas Ukachukwu ló jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò Abẹ́lé ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó wáyé ní ìlú Okwa ní àná.
Ìbò ọ̀tàlélégbèje ó dín márùn-ún (1455 votes) ló ní.Nigbà tí Valentine Ozigbo tó tẹ̀le ní mẹ́tàdínláàádọ́rin (67 votes) Johnbosco Onunkwo ní tirẹ̀ ní ìbò mẹ́rìdínlọ́gbọ̀n(26 votes),Edozie Madu ló ru póò pẹ̀lú ìbò mẹ́jọ péré.
Nígbà tó ń sọ ọ̀rọ̀ ‘Mo gbà’ Ukachukwu ní “O pẹ́ tí mo ti ń fọba jẹ ní ìpínlẹ̀ Anambra,Ní báyìí, èmi ló kàn.Kò sí gómìnà kan tó jé ní ìpínlẹ̀ yìí tí kò gba ore -ọ̀fẹ́ mi, ṣùgbọ́n ó tó gẹ́ẹ́,alubàtá kìí dá orin èmi náà fi jẹ gómìnà”
Ó wá rọ àwọn ènìyàn tí wọ́n dìjọ díje kí wọ́n fọwọ́ ṣọwọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti le jáwé Olúborí nínú ètò ìdìbò sí ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ náà ti yóò wáyé ní inú oṣù kọkànlá ọdún yìí.
Ní báyìí tí Ukachukwu tí di àsíá ẹgbẹ́ APC mú, òun àti George Mohalu ti ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party pẹ̀lú Gómìnà Charles Soludo tó wà lórí àpèrè lọ́wọ́ tó sì ń dije lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APGA ni wọn yóò máa fi iga gbága nínú osù kọkànlá ọdún yìí tí ìdìbò yóò wáyé

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
