Mọ̀dàrú ni Obi àti Otti…. Faruk

Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party nílẹ̀ wa Nàìjíríà ti fẹ̀ṣùn kan Olùdíje fún ipò Ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún ní ọdún 2023, Ọ̀gbẹ́ni Peter Obi àti Gómìnà ìpínlẹ̀ Ábíá, Ọ̀gbẹ́ni Alex Otti pé àwọn méjèèjì ni igi wọ́rọ́kọ́ tó ń da iná rú àti àrò wọ̀rọ̀kọ̀ tó ń da ọbẹ̀ í nù nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà.

Àná ni ìgbìmò aláṣẹ ẹgbẹ́ ti a mọ̀ sí NWC ti Umar Farouq ṣojú fún fi ọ̀rọ̀ yìí léde ní ìlú Abuja.Farouq ní ó ya àwọn lẹ́nu pé Peter Obi àti Gómìnà Alex Otti ti gbogbo àwọn ènìyàn rò pé ẹní mimọ tí kò lè ró ìwà ìbàjẹ́ mọ́ etí aṣọ ni wọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí a gbójú okùn lé kò jọ ẹni agba ni ọ̀rọ̀ náà.Bíi kó-wó-kó-wó ti ìrókò ń wo àràbà ni Obi àti Otti ń wo ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ṣùgbọ́n èrò wọn kò ní jọ.

Wọ́n wá pa ẹnu pọ̀ ṣe ṣàmá-ń-sáńgúdù sí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ fún ìdájọ́ tó gbé kalẹ̀ níbi tó ti ti ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó yọ Abure nípò sígbó tó sì gbé adé fún ẹni tó ladé.Èyí túmọ̀ sí pé tàbí-ṣùgbọ́n kò sí níbẹ̀,Abure ló ni Labour Party lónì-ín.Wọ́n wá rọ gbogbo ẹni tí inú ń bí kí wọ́n ti idà wọn bọ àkọ̀.

Títí di àsìkò ti a ń kó ìròyìn yìí jọ,Peter Obi àti Gómìnà ìpínlẹ̀ Ábíá Ọ̀gbẹ́ni Alex Otti kò tíí ṣẹ́ ẹsùn náà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×