Ṣe Àḿbọ̀dé ń Padà bọ ni?

Kò sí ẹni tó lè sọ ìgbà tí òjò òṣèlú tó ṣú ní ìpínlẹ̀ Èkó yóò rọ̀ tàbí sọ irú ẹni tí yóò pa. Oníkálukú nínú àwọn tó ń gbìyànjú láti di gomina ipinle Eko ní ọdún 2027 ló ti ń gbìyànjú láti ṣètò tí iyọ̀ yóò fi dun ti wọn.

Bí ènìyàn bá ń wo bí ètò òṣèlú ipinle Eko se ń lọ, lára àwọn tí ẹnu ń kùn ni Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ náà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yìí ní sáà, ìyẹn, Mudasiru Ọbasá,Seyi Tinúbú,Fẹ́mi Gbàjàbíàmílà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ olóṣèlú mìíràn ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Ọ̀kan gbòógì tí ẹnu tún ń kùn ni Gómìnà àná ni ipinle Eko,Akínwùmí Àḿbòde.Bí a bá wò ó fínnífínní,Àḿbòde nìkan ní gómìnà tó jẹ ní ìpínlẹ̀ Èkó tí kò ní ànfààní láti lo sáà méjì láti ọdún 1999 tí ètò òṣèlú Alágbádá tí a ń lò yìí ti bẹ̀rẹ̀.

Ìdí sì rèé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ àti àwọn ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ náà fi ní dandan ni kó padà wá láti parí sáà tí òfin gbà á láàyè láti lò nítori kò sí bí ọbọ ṣe ṣe orí tí ìnàkí kò ṣe.Fún ìdí èyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpàdé òṣèlú ló ti ń lọ lábẹ́nú tí ìfikùnlukùn sì ń tẹ̀ síwájú láti rí i pé kinní náà já mọ́ Àḿbòde lọ́wọ́.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×